Anglican Hymnal
Uncreated Fount of light
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 302: Uncreated Fount of light
Iwo Isun imole
Hymn:
302
Meter:
7.7.7.7
Season:
Litani si Baba Aiyeraiye
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
APA I
Iwọ Isun imọlẹ;
Ogo ti kò l’okunkun;
Aiyeraiye, titi lai,
p
Baba Mimọ, gbọ ti wa.
Kanga Iye ti nṣàn lai;
Iye ti kò l’ abawọn,
Iye t’o ni irọra,
di
Baba Mimọ, gbọ ti wa.
p
Olubukun, Olufẹ,
Ọmọ Rẹ mbẹ̀ Ọ loke;
Ẹmi Rẹ nradọ bò wa;
Baba Mimọ, gbọ ti wa.
mf
Y’ itẹ safire Rẹ ka
L’ oṣumare ogo ntàn:
p
O kun fun alafia,
Baba Mimọ, gbọ ti wa.
mf
N’ iwaju ‘tẹ anu Rẹ
L’ awọn Angẹli npade,
p
Ṣugbọn wò wa lẹsẹ Rẹ,
Baba Mimọ, gbọ ti wa.
mp
Iwọ ti ọkàn Rẹ nyọ́
S’ amuṣua t’ o pada,
T’O mọ̀ ‘rìn rẹ̀ lokere,
p
Baba Mimọ, gbọ ti wa.
pp
Ọkàn ti nwá isimi;
Ọkàn t’ ẹ̀ru ẹ̀ṣẹ npa;
B’ ọm’-ọwọ ti nke f’ọmu,
p
Baba Mimọ, gbọ ti wa.
cr
Gbogbo wa ni alaini
L’ ebi, l’ ongbẹ at’ arẹ̀;
Kò si ède f’ aini wa,
p
Baba Mimọ, gbọ ti wa.
mf
Iṣura ọpọlọpọ
Kọ l’ O kojọ bi Ọba?
Ainiye, aidiyele?
p
Baba Mimọ, gbọ ti wa.
mp
‘Wọ kò da Ọmọ Rẹ si,
Ọmọ Rẹ kanṣoṣo na,
Tit’ O fi par’ iṣẹ Rẹ,
p
Baba Mimọ, gbọ ti wa.
APA II
mp
‘Wọ t’O sunmọ, gb’ O nkẹdùn,
T’ O gbọ ‘gbe Rẹ̀ ikẹhin;
T’O jọwọ Rẹ̀ lati ku.
Baba Mimọ, gbọ ti wa.
p
Iwọ ti o le gbà ni
L’ọwọ ìji iparun,
L’ọwọ ‘boji at’ iku.
pp
Baba Mimọ, gbọ ti wa.
f
‘Wọ lọw’ ọtun Ẹniti
On joko nisisiyì,
T’O gunwà bi t’ iṣaju
p
Baba Mimọ, gbọ ti wa.
f
Wọ t’o f’ ore de l’ade,
T’O sì gbe mọ aiya Rẹ,
On n’ Imọlẹ oju Rẹ.
p
Baba Mimọ, gbọ ti wa.
f
Gbogb’ ẹ̀bun meje ọrun,
Lọdọ Ẹmi meje nì
L’ okọ Olurapada.
p
Baba Mimọ, gbọ ti wa.
mf
L’ aṣẹ Rẹ̀ ni Ẹmi wá,
‘Mọlẹ̀ at’ ẹ̀la ahọn,
L’ okọ Olurapada.
p
Baba Mimọ, gbọ ti wa.
Fun wa li akoko yi,
Lat’ inu ẹ̀bun Rẹ wá,
‘Mọlẹ, ìye, agbara.
Baba Mimọ, gbọ ti wa.
p
Gbọ́ ‘gbe wa, gbọ́ aini wa;
pp
Gbọ́, Ẹmi mbẹbẹ n’nu wa:
cr
Gbọ́, tori Jesu nṣìpẹ.
p
Baba Mimọ, gbọ ti wa. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites