Anglican Hymnal
There is an eye that never sleeps
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 301: There is an eye that never sleeps
Oju kan mbe ti ki togbe
Hymn:
301
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Adura
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Oju kan mbẹ ti ki togbe,
Nigbat’ ilẹ ba ṣú;
Eti kan si mbẹ ti kì ise,
‘Gbati orùn ba wọ̀.
Apa kan mbẹ, ti kò lè rẹ̀,
‘Gba ‘pa enia pin;
Ifẹ kan mbẹ, ti kò lè kù,
‘Gba ‘fẹ aiye ba kù.
Oju na nwò awọn Seraf,
Apa nà d’ọrun mu;
Eti na kun f’orin Angẹl,
Ifẹ na ga lokè.
mp
Ipa kan l’ enia lè lò,
‘Gbat’ ipa gbogbo pin;
Lati ri oju at’ apa,
Ati ifẹ nla nà.
cr
Ipa na ni adurà wa,
Ti nlọ ‘waju itẹ;
f
T’o nmi ọwọ t’o s’aiye ró,
Lati mu ‘gbala wá.
mp
Iwọ t’anu Rẹ tò lopin,
T’ifẹ Rẹ kò le ku:
f
Jẹ k’ a n’ igbagbọ at’ ifẹ,
cr
K’a le ma gbadurà. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites