Anglican Hymnal
From every stormy wind that blows
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 299: From every stormy wind that blows
Ninu gbogbo iji ti nja
Hymn:
299
Meter:
L.M (8.8.8.8)
Season:
Adura
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Ninu gbogbo ìji ti nja,
Ninu gbogbo ìgbi ‘pọnju,
Abò kan mbẹ, ti o daju;
p
O wà labe itẹ-anu.
mf
Ibi kan wà ti Jesu ndà
Ororo ayọ̀ s’ ori wa;
O dùn ju ibi gbogbo lọ;
p
Itẹ̀-anu t’ a f’ẹjẹ wọ̀.
f
Ibi kan wà fun idapọ̀
Nibi ọ̀rẹ́ npade ọ̀rẹ́;
Lairi ‘ra, nipa igbagbọ,
p
Nwọn y’ itẹ-anu kanna ka.
f
A ! nibo ni a ba sá si,
Nigba ‘danwo at’ ipọnju?
A ba ṣe le bori Eṣu,
p
Boṣepe kò si ‘tẹ-anu?
f
A ! bi idi l’a fò sibẹ,
B’ẹnipe aiye kò si mọ,
Ọrun wa ‘pade ọkàn wa,
p
Ogo si bò itẹ-anu. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites