Anglican Hymnal
Pray, always pray; the Holy Spirit pleads
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 298: Pray, always pray; the Holy Spirit pleads
Ma gbadura
Hymn:
298
Meter:
10.10
Season:
Adura
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Ma gbadurà; Ẹmi mbẹbẹ n’nu rẹ
Fun gbogbo aini rẹ igbagbogbo.
mp
Ma gbadurà; labẹ ẹrù ẹ̀ṣẹ
Adurà nri ẹ̀jẹ Jesu ti nṣàn.
Ma gbadurà; b’ arẹ tilẹ mu ọ,
Adurà ngbe wa s’ẹba ‘tẹ Baba,
cr
Ma gbadurà; n’nu wahala aiye,
Adurà l’o nfun ọkàn n’ isimi.
f
Ma gbadurà; b’ayọ̀ ba yi ọ ka,
cr
Adurà nlù harp, o nkọrin angẹl’.
p
Ma gbadurà; b’awọn t’o fẹran ku,
cr
Adurà mba wọn mu omi ìye.
di
Gbogb’ ohun aiye y’o b’aiye kọja,
mf
Adurà wà titi: ma gbadurà. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites