Anglican Hymnal
Father of mercies, in thy word
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 295: Father of mercies, in thy word
Baba orun, nin’ oro Re
Hymn:
295
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Oro Olorun
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Baba ọrun, nin’ọ̀rọ Rẹ
Ni ogo ọrun ntàn;
Titi lai l’a o ma yin Ọ
Fun Bibeli mimọ.
mp
Ọpọ ‘tunu wà ninu rè,
Fun ọkàn alarẹ̀;
Gbogbo ọkàn ti ongbẹ ngbẹ,
Nri omi iye mu.
f
Ninu rẹ̀ l’alafia wà,
Ti Jesu fi fun wa;
Iye ainipẹkun si wà,
N’nu rẹ̀ fun wa gbogbo.
mf
Iba lè ma jẹ ayọ̀ mi,
Lati ma ka titi;
cr
Ki mma ri ọgbọn titun kọ,
N’nu rẹ̀ lojojumọ.
mf
Oluwa Olukọ ọrun,
Màṣe jina si mi;
Kọ mi lati fẹ ọ̀rọ Rẹ,
Ki nri Jesu nibẹ. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites