Anglican Hymnal

There is a book, who runs may read

Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.

Hymn 294: There is a book, who runs may read

Iwe kan wa ti kika re

Hymn: 294
Meter: C.M (8.6.8.6)
Season: Oro Olorun
Add Favourite
  1. mf Iwe kan wa ti kika rẹ̀,
    Kò ṣoro fun enia,
    Ọgbọn ti awọn t’o ka nfẹ,
    Ni ọkàn ti o mọ́.

  2. Iṣẹ gbogbo t’Ọlọrun ṣe,
    L’oke, n’ilẹ; n’nu wa;
    Nwọn j’ọkan ninu iwe na,
    Lati f’Ọlọrun hàn.

  3. mf Imọlẹ oọupa l’oke,
    Lat’ ọdọ orùn ni;
    Bẹ l’ogo Ijọ Ọlọrun,
    T’ọdọ Ọlọrun wá.

  4. mf Iwọ ti O jẹ ki a ri,
    Ohun t’o dara yi:
    Fun wa l’ọkàn lati wá Ọ,
    K’a ri Ọ nibi gbogbo. Amin.