Anglican Hymnal
We give immortal praise
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 288: We give immortal praise
Mo f’ iyin ailopin
Hymn:
288
Meter:
6.6.6.6.8.8
Season:
Ojo Metalokan
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Mo f’iyin ailopin
Fun Ọlọrun Baba,
Fun ore aiye mi,
At’ ireti t’ọrun.
O ran Ọmọ Rẹ̀ ayanfẹ,
p
Lati ku fun ẹṣẹ aiye.
f
Mo f’iyin ailopin
Fun Ọlọrun Ọmọ;
p
T’ O f’ ẹjẹ Rẹ̀ wẹ̀ wa,
Kuro ninu egbé;
Nisisiyi O wà l’Ọba,
O nri eso irora Rẹ̀.
f
Mo f’iyin ailopin
Fun Ọlọrun Ẹmí:
Ẹni f’ agbara Rẹ̀,
Sọ ẹlẹṣẹ d’ ayè.
O pari iṣẹ igbala,
ff
O si fi ayọ kun ọkàn.
f
Mo f’iyin ailopin
Fun Olodumare,
‘Wọ Ologo mẹta,
Ṣugbọn ọ̀kanṣoṣo;
B’ O ti ju imọ̀ wa lọ nì,
ff
A o ma f’ igbagbọ yin Ọ. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites