Anglican Hymnal
Spirit blest, Who art adored
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 279: Spirit blest, Who art adored
Emi ’bukun ti a nsin
Hymn:
279
Meter:
7.7.7.7
Season:
Ojo Isimi Funfun
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Ẹmi ‘bukun ti a nsìn
Pẹlu Baba at’ Ọrọ,
Ọlọrun aiyeraiye;
p
Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
cr
Ẹmi Mimọ, ‘Daba ọrun,
Irì ti nsẹ̀ lat’ òke,
Ẹmi ‘yè at’ iná ‘fẹ;
p
Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
mf
Isun ipá at’ ìmọ,
Ọgbọn at’ ìwa-mimọ,
Oye, imọran, ẹ̀ru;
p
Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
mf
Isun ifẹ, alafia,
Suru, ibisi ‘gbagbọ,
‘Reti, ayọ̀ ti ki tan;
p
Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
cr
Ẹmi Afọnahan ni,
Ẹmi ti nmú ‘mọlẹ wá,
Ẹmi agbara gbogbo;
p
Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
mp
‘Wọ t’o mu Wundia bi,
Ẹni t’ ọrun t’ aiye mbọ,
T’a ran lati tun wa bi;
p
Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
cr
‘Wọ ti Jesu t’ oke ran
Wa tu enia Rẹ̀ ninu,
Ki nwọn má ba nikan wà,
p
Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
Wọ t’O nf’ore kun Ijọ,
T’O nfi ifẹ Baba han,
T’O nmu k’o ma ri Jesu;
p
Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
mf
Wo ti nf’ onjẹ iye,
At’ otitọ na bọ́ wa,
Ani, On t’O ku fun wa;
p
Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
F’ẹ̀bun meje Rẹ fun ni,
Ọgbọn, lati m’Ọlọrun,
Ipá lati kò ọta;
p
Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
mf
Pa ẹ̀ṣẹ run lọkà wa,
To ifẹ wa si ọ̀na,
B’a ba nṣẹ̀ Ọ, mu surù,
p
Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
cr
Gbe wa dide, b’a ṣubu,
Ati nigba idanwo,
Sa pè wa pada pẹ̀l´;
p
Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
mf
Wá, k’O mu ailera le,
F’igboiya fun alarẹ,
Kọ wa l’ọ̀rọ t’a o sọ;
p
Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
mf
Wá ràn ọkàn wa lọwọ,
Lati mọ̀ otitọ Rẹ,
Ki ‘fẹ wa le ma gbona;
p
Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
mf
Pa wa mọ l’ọna toro
Ba wa wi nigb’a nṣako,
Ba wa bẹbẹ l’ adura,
p
Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
f
Ẹni Mimọ, Olufẹ,
Wá gbe inu ọkàn wa;
Ma fi wa silẹ titi:
p
Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites