Anglican Hymnal
O Holy Dove, from heav’n descend
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 270: O Holy Dove, from heav’n descend
Adaba orun, sokale
Hymn:
270
Meter:
L.M (8.8.8.8)
Season:
Ojo Isimi Funfun
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Adaba ọrun, sọkalẹ̀,
Gbe wa lọ l’apa iyẹ Rẹ;
f
Ki o si gbe wa ga soke,
Jù gbogbo ohun aiye lọ.
mf
Awa iba lè ri itẹ
Olodumare Baba wa,
p
Olugbala joko nibẹ,
O gunwà l’awọ̀ bi tiwa.
cr
Ẹgbẹ mimọ́ duro yi ká,
Itẹ, Agbara wolẹ̀ fun,
Ọlọrun hàn ninu ara,
O si tàn ogo yi wọn ka.
f
Oluwa, akokò wo ni
Emi o de bugbe loke?
T’ emi o ma ba wọn wolẹ̀,
Ki mma sìn Ọ, ki mma kọrin? Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites