Anglican Hymnal
We speak of the realms of the Blest
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 261: We speak of the realms of the Blest
A nsoro ile ’bukun ni
Hymn:
261
Meter:
8.9.8.8
Season:
Oke Orun
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
A nsọ̀rọ ilẹ ‘bukun nì,
Ilẹ didan, at’ ilẹ ẹwà;
‘Gbagbogbo l’a nsọ t’ogo rẹ̀;
p
Y’o ti dùn tó lati de ‘bẹ!
mf
A nsọ̀rọ ita wura rẹ̀,
Ọṣọ odi rẹ̀ ti kò l’ẹgbẹ;
‘Fajì rẹ̀ kò ṣe f’ẹnu sọ;
p
Y’o ti dùn tó lati de ‘bẹ!
mf
A nsọ p’ ẹṣẹṣ kò si nibẹ,
Kò s’aniyan at’ ibanujẹ,
Pẹlu ‘danwo lode, ninu;
p
Y’o ti dùn tó lati de ‘bẹ!
mf
A nsọrọ orin iyìn rẹ̀,
Ti a kò le f’orin aiye wé;
B’o ti wù k’orin wa dùn to;
p
Y’o ti dùn tó lati de ‘bẹ!
mf
A nsọrọ isin ifẹ rẹ̀,
Ti agbada t’ awọn mimọ nwọ̀,
Ijọ akọbi ti oke;
p
Y’o ti dùn tó lati de ‘bẹ!
mf
Jọ, Oluwa, t’ibi t’ire,
Sa ṣe ẹmi wa yẹ fun ọrun;
Laipẹ, awa na yio mọ̀,
p
Y’o ti dùn tó lati de ‘bẹ̀. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites