Anglican Hymnal
After this dismal and dark world
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 258: After this dismal and dark world
Lehin aiye okunkun yi
Hymn:
258
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Oke Orun
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Lẹhìn aiye òkunkun yi,
Ogo ailopin mbẹ;
At’ilu ayọ̀ ti ki tan,
T’ oju ẹda ko ri.
Ilu ẹwa! oju wa ‘ba
Ri ‘daji ayọ́ rẹ,
Ọkan wa iba ti fẹ to
Lati f’ aiye silẹ!
p
Aìsan on ‘rora ki de ‘bẹ̀,
cr
Ibanujẹ kò si;
f
Ilera ni lọjọ gbogbo,
Adùn ti kò lopin.
mf
Oru kó si n’ ilu wọnnì,
Ọsan ni titi lai;
Ẹṣẹ, orison ègbé wa,
Kò le wọ̀ ‘bẹ̀ titi.
f
A! k’ ireti ọrun wa yi
Mu ọkàn wa gbóna,
K’ igbagbọ at’ ifẹ nla yi
M’ èro wa lọ soke.
Oluwa, ‘lanu ṣe wa yẹ
Fun àgbalá ọrun;
f
Si sọ f’ọkàn wa k’o dide
Dapọ m’ awọn t’ ọrun. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites