Anglican Hymnal
A mount exist so high and bright!
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 257: A mount exist so high and bright!
Oke kan mbe t’ o ga
Hymn:
257
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Oke Orun
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Oke kan mbẹ t’ o ndan t’ o ga,
Nibi t’ a m’ Ọlọrun;
O wà l’ okerè ni ọrun,
Itẹ Ọlọrun ni.
mf
Tal’ awọn t’o sunmọ ibẹ̀,
Lati wò itẹ Rẹ̀?
Ẹgbarun wọn t’ o wà nibẹ̀,
Ọmọde bi awa.
Olugbala w’ ẹ̀ṣẹ wọn nù,
O sọ wọn di mimọ́;
Nwọn f’ ọ̀rọ Rẹ̀, nwọn f’ ọjọ Rẹ̀,
Nwọn fẹ, nwọn si ri i.
mf
Labẹ ọpọ oko tutú,
p
L’ara wọn simi si:
Nwọn ri ‘gbala ọkàn wọn he,
Laiya Olugbala.
f
K’ awa k’ o rìn bi nwọn ti rìn,
Ipa t’ o lọ s’ọrun;
Wá idariji Ọlọrun,
T’ o ti dariji wọn.
p
Jesu ngbọ́ irẹlẹ ẹkun,
T’ o mu ọkàn d‘ ọtun;
Lori òke t’ o ndán, t’ o ga,
f
L’ awa o ma wo Ọ. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites