Anglican Hymnal
Jerusalem on high
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 255: Jerusalem on high
Jerusalem t’ orun
Hymn:
255
Meter:
6.6.6.6.4.4.4.4
Season:
Oke Orun
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Jerusalem t’ọrun,
Orin mi, ilu mi!
Ile mi bi mba kú,
Ẹkún ibukun mi;
cr
Ibi ayọ̀!
Nigbawo ni,
Ngo r’oju rẹ,
Ọlọrun mi?
mf
Odi rẹ, ilu mi,
L’ a fi pearl ṣe l’ ọ̀ṣọ́;
f
‘Lẹ̀kun rẹ ndan fun yìn,
Wura ni ita rẹ!
cr
Ibi ayọ̀ &c.
mp
Orùn ki ràn nibẹ,
Bẹni kò s’ oṣupa;
A kò wa iwọnyi,
Krist n’ imọlẹ ibẹ.
cr
Ibi ayọ̀ &c.
mf
Nibẹ l’ Ọba mi wà,
p
T’ a dá l’ ẹbi l’ aiye;
f
Angẹli nkọrin fun,
Nwọn si ntẹriba fun.
cr
Ibi ayọ̀ &c.
Patriark’ igbani,
Par’ ayọ wọn nibẹ;
Awọn woli, nwọn nwò
Ọmọ alade wọn.
cr
Ibi ayọ̀ &c.
mf
Nibẹ ni mo lè ri
Awọn Apostili;
At’ awọon akorin,
Ti nlù harpu wura,
cr
Ibi ayọ̀ &c.
mp
Ni agbala wọnni,
Ni awọn Martir wà;
cr
Nwọn wọ̀ aṣọ àla,
Ogo bo ọgbẹ wọn.
Ibi ayọ̀ &c.
p
T’ emi yi sa su mi,
Ti mo gb’ agọ Kedar
Ko si ‘ru yi loke:
cr
Nibẹ ni mo fẹ lọ.
f
Ibi ayọ̀ &c. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites