Anglican Hymnal
Where high the heavenly temple stands
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 252: Where high the heavenly temple stands
Olor’ Alufa giga kan
Hymn:
252
Meter:
L.M (8.8.8.8)
Season:
Oke Orun
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Olor’ Alufa giga kan,
To gb’ẹda wa wọ̀ farahan,
Nibit tempil’ ọrun wà,
Ile Ọlọrun t’a kò kọ́.
p
On, bi Onigbọwọ enia,
To t’ẹjẹ ‘yebiye s’ile,
To npari ‘ṣẹ nla Rẹ̀ l’ọrun,
Olugbala, Ọrẹ enia.
mf
B’o tilẹ goke lọ s’ọrun,
O nfoju ifẹ wò aiye,
Ẹnit’o njẹ́ okọ enia,
O mọ̀ ailera ẹda wa.
mp
Alabajiya wa si mọ̀
Bi ‘rora wa si ti pọ to;
di
L’ọrun, o si nranti sibẹ,
pp
Omije on ‘waiya jà Rẹ̀.
mp
Ninu ibanujẹ ọkàn,
Ẹni ‘Banujẹ pin n’nu Rẹ̀;
cr
O mba wa daro ẹ̀dun wa,
O si nràn òjiya lọwọ.
f
K’ a k’ẹdùn wa lọ sọdọ Rẹ̀,
Pẹlu ‘gboiya, nibi itẹ;
K’a tọrọ agbara ọrun,
Lati yọ wa nigba ibi. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites