Anglican Hymnal
O hear the song of rejoicing in heaven
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 246: O hear the song of rejoicing in heaven
E gbo iro orin ayo orun
Hymn:
246
Meter:
10.10.10.10
Season:
Igoke Re Orun
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Ẹ gbọ́ ìro orin ayọ̀ ọrun,
Orin ayọ̀ ti iṣẹgun Jesu;
Gbogbo ọta l’o tẹri wọn ba fun,
p
Ẹṣẹ, ikú, isa-okú pẹlu.
f
O ṣe tan lati lọ gba ijọba,
Fun Baba, Ọlọrun ohun gbogbo;
O ṣe tan lati lọ gbà iyin nla,
T’ o yẹ Olori-ogun ‘gbala wa.
p
Ohun ikanu ni lilọ Rẹ̀, fun
Awọn ayanfẹ ọmọ-ẹhin Rẹ̀.
f
Ẹ má ṣe kọnnu l’ ọrọ itunu,
“Emi nlọ pèse àyé nyin silẹ̀”.
Ọrun gba lọ kuro lẹhin eyi,
Awọsanma se Olugbala mọ;
ff
Awọn Ogun-ọrun hó fun ayọ̀,
Fun bibọ̀ Kristi Oluwa ogo.
mp
Ẹ maṣe ba inu nyin jẹ rara,
Jesu, ireti wa, yio tun wa;
f
Yio wa mu awọn enia Rẹ̀ lọ,
Sibiti nwọn o ba gbe titilai. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites