Anglican Hymnal
God is gone up on high
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 244: God is gone up on high
Olorun goke lo
Hymn:
244
Meter:
6.6.6.6.8.8
Season:
Igoke Re Orun
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Ọlọrun goke lọ,
Pẹlu ariwo nla;
Awọn ipè ọrun
Nfi ayọ̀ Angẹl hàn;
ff
Gbogbo aiye yọ̀, k’ ẹ gberin,
Ẹ f’ogo fun Ọba Ogo.
mp
O j’ enia laiye,
f
Ọba wa ni lokè;
Ki gbogbo ilẹ mọ̀
Ifẹ nla Jesu wa;
ff
Gbogbo aiye, &c.
f
Baba fi agbara
Fun Jesu Oluwa;
Ogun Angẹl mbọ Ọ,
On l’Ọba nla ọrun;
ff
Gbogbo aiye, &c.
f
L’ or’ itẹ Rẹ̀ mimọ́,
O gb’ ọpa ododo;
Gbogbo ọ̀ta Rẹ̀ ni
Yio ka lọ bẹrẹ.
ff
Gbogbo aiye, &c.
f
Ọta Rẹ̀ l’ọta wa,
Eṣu, aiye, ẹ̀ṣẹ;
Ṣugbọn y’o r’ẹhin wọn,
Ijọba Rẹ̀ y’o de.
ff
Gbogbo aiye yọ̀, k’ ẹ gberin,
Ẹ f’ogo fun Ọba Ogo. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites