Anglican Hymnal
O Thou God of Heaven
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 24: O Thou God of Heaven
Olorun wa Orun
Hymn:
24
Meter:
S.M (6.6.8.6)
Season:
Ojo Oluwa
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Ọlọrun wa Ọrun,
T’ o fi ọjọ mẹfa
Da nkan gbogbo ti mbẹ laiye
Simi n’ ọjọ keje.
f
O paṣẹ k’a bọ̀wọ
Fun ọjọ isimi;
Ibinu Rẹ̀ tobi pupọ
S’ awọn t’ o rufin yi.
Awọn baba nla wa,
p
Ti kù nin’ okunkun;
Nwọn jẹ ògbó abọriṣa
Nwọn kò mọ̀ ofin Rẹ.
mf
Awa de Oluwa,
Gẹgẹ bi aṣẹ Rẹ;
Lẹhin iṣẹ ijọ mẹfa,
Lati ṣe ifẹ Re.
mf
Mimọ̀ l’ ọjọ oni,
O yẹ ki a simi,
K’ a pejọ ninu ile Rẹ,
K’ a gbọ ‘rọ mimọ Rẹ.
Isimi nla kan kù
F’ awọn enia Re;
Ọm’ Ọlorun, Alabukun
Mu wa de ‘simi Rẹ ! Amin
« Back to Hymn List
View Favourites