Anglican Hymnal

What are those Sabbaths of joy without end

Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.

Hymn 239: What are those Sabbaths of joy without end

Kini ’simi ayo ailopin ni

Hymn: 239
Meter: 10.10.10.10
Season: Ojo Oluwa lehin Ajinde
Add Favourite
  1. mf Kini ‘Simi ayọ ailopin nì,
    T’ awọn angẹl at’ awọn mimọ ni?
    mp ‘Simi f’ alarẹ̀; f’ awọn asẹgun,
    f Nibẹ l’ Ọlọrun jẹ ohun gbogbo.

  2. mf ‘Tal’ Ọba na? tani yi ‘tẹ Rẹ̀ ka?
    p Irọra itura Rẹ ha ti ri?
    mf Sọ funni, ẹnyin ti njọsin nibẹ;
    Sọ funni, b’ ọrọ to t’ ayọ nyin so.

  3. Jerusalem totọ, ilu mimọ,
    Alafia eyit’ o jẹ kik’ ayọ;
    A r’ ohun t’a nfẹ n’nu rẹ k’a to wi,
    A si rigbà jù eyit’ a nfẹ lọ.

  4. L’ agbala Ọba wa, wahala tán,
    Laibẹ̀ru l’a o ma kọrin Sion,
    Oluwa, niwaju Rẹ lao ma fi
    Idahun ‘fẹ hàn f’ẹbun Ifẹ Rẹ.

  5. cr ‘Simi kò le tẹle ‘Simi nibẹ;
    Ẹnikan ni ‘Simi ti nwoju Rẹ.
    f Nibẹ orin jubeli kò le tan,
    mp T’ awọn mimọ at’ angẹli y’o kọ.

  6. cr L’ aiye yi, pẹlu ‘gbagbọ at’ adua,
    L’ ao ma ṣafẹri ‘le Baba ọ̀hun;
    f Si Salem l’awọn ti a ṣi nipo
    mp Npada lọ; --- lat’ ilu Babiloni.

  7. p Njẹ awa tẹriba niwaju Rẹ,
    cr T’ Ẹniti ohun gbogbo jasi;
    mf Ninu eniti Baba at’Ọmọ,
    T’ Ẹniti Ẹmi jẹ́ Ọkanso lai. Amin.