Anglican Hymnal
Oh, Our Heavenly Lord
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 238: Oh, Our Heavenly Lord
Oluwa wa orun
Hymn:
238
Meter:
6.6.6.6.8.8
Season:
Ojo Oluwa lehin Ajinde
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Oluwa wa ọrun!
Agọ Rẹ laiye yi,
Ibugbe ifẹ Rẹ,
Ẹwà rẹ̀ ti pọ̀ to!
ff
Ọkàn mi nfà
Lati goke
S’ ibugbe Rẹ,
Ọlọrun mi.
mf
Ayọ̀ b’awọn ti nsìn,
Nibit’ Ọlọrun yàn;
Ti nwọn npara ibẹ,
Lati má jọsin wọn;
ff
Nwọn nyin Ọ ṣa:
Ayọ̀ b’ awọn
T’ o fẹ ọna
Oke Sion.
f
Lati ipá de ‘pá
Laiye òṣi wa yi:
Titi nwọn fi goke,
Ti nwọn si yọ ọ’ọrun:
ff
‘Bugbe ogo!
‘Gbat’ Ọlọrun
Ba m’ ẹsẹ wa
De ibẹ̀ ná.
mf
Ọlọrun l’ asa wa,
Imọlẹ at’ odi;
Ọwọ rẹ̀ kún f’ ẹ̀bun,
A ngbà ‘bukun nibẹ:
ff
Ayọ̀ pupọ
Ni fun awọn
T’o gbẹkẹle
Ọlọrun wa. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites