Anglican Hymnal
I am telling, each, everyone
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 233: I am telling, each, everyone
Mo wi fun olukuluku
Hymn:
233
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Ajinde Jesu
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Mo wi fun olukuluku
f
Pe, On ji, O si yè;
O si wà larin wa pẹlu,
Nipa Ẹmi iyè.
Ẹ wi fun ẹnikeji nyin,
Ki nwọn ji pẹlu wa,
K’ imọlẹ k’ o wà kakiri
Ni gbogbo aiye wa.
Nisisiyi aiye yi ri
Bi ile Baba wa:
Iyè titun ti On fun ni,
O sọ d’ ile Baba.
mf
Ọna okùn ti On ti rin
Mu ni lọ si ọrun;
Ẹnit’ o rìn bi On ti rìn,
Y’o d’ ọdọ Rẹ̀ l’ọrun.
f
On yè, O si wà pẹlu wa,
Ni gbogbo aiye yi;
Ati nigba’ a f’ ara wa,
F’ erupẹ ni ‘reti. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites