Anglican Hymnal
Jesus the friend of sinners dies
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 232: Jesus the friend of sinners dies
Jesu ore elese ku
Hymn:
232
Meter:
L.M (8.8.8.8)
Season:
Ajinde Jesu
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
p
Jesu ọrẹ ẹlẹṣẹ kú,
Awọn ọmọ Salem nsọkun:
Okunkun bo oju ọrun,
Iṣẹlẹ nla ṣẹ̀ lojiji.
Nihin l’ a r’ anu ar’ ifẹ,
p
Ọba ogo kú f’ enia;
Wo! ayọ̀ ki l’ a tun ri yi,
Jesu t’ O kú tun ji dide.
f
Má bẹ̀ru mọ, ẹnyin mimọ́;
Sọ bi Oluwa ti jọba;
Kọrin b’ O ti ṣẹgun Eṣu,
f
Bi O si ti bori ikú.
ff
Ẹ wipe, “Ọba, wà titi,
Iwọ t’ a bi lati gbà wa;”
K’ ẹ bi ikú pe, “Oró rẹ dá?”
“Iboji, iṣẹgun rẹ dà?” Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites