Anglican Hymnal

If sinners join their hands

Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.

Hymn 230: If sinners join their hands

B’ elese s’ owo po

Hymn: 230
Meter: 6.6.6.6.4.4.4.4
Season: Ajinde Jesu
Add Favourite
  1. ff B’ ẹlẹṣẹ s’ ọwọ po,
    Ti nwọn nde s’Oluwa,
    Dimọ si Kristi Rẹ̀,
    Lati gan Ọba na,
    B’ aiya ṣata,
    Pẹlu Eṣu,
    Eke ni nwọn,
    Nwọn nṣe lasan.

  2. f Olugbala jọba !
    Lori oke Sion;
    Aṣẹ ti Oluwa
    ff Gbe Ọmọ Tirẹ̀ ro:
    Lati boji
    O ni, k’ O nde,
    K’ O si goke,
    K’ O gba ni là.

  3. mf F’ ẹru sìn Oluwa,
    Si bọwọ f’ aṣẹ Rẹ̀;
    F’ ayọ̀ wá sọdọ Rẹ̀,
    F’ iwariri duro;
    p Ẹ kunlẹ fun,
    K’ ẹ tẹriba;
    Sọ t’ ipa Rẹ̀,
    Ki Ọmọ na. Amin.