Anglican Hymnal
Jesus lives! Thy terrors now
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 219: Jesus lives! Thy terrors now
Jesu ye; titi aiye
Hymn:
219
Meter:
7.8.7.8.4
Season:
Ajinde Jesu
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Jesu yè; titi aiye
Ẹru ikú kò bà ni mọ;
Jesu yè; Nitorina
Isa okù kò n’ ipa mọ.
Alleluya !
mf
Jesu yè; lat’ oni lọ,
Ikù jẹ ọ̀na si ìye;
di
Eyi y’o jẹ ‘tunú wa,
‘Gbat’ akoko ikú ba de.
Alleluya !
mp
Jesu yè; fun wa l’ o kú,
cr
Njẹ Tiré ni a o ma ṣe;
A o f’ ọkan funfun sìn,
A o f’ ogo f’ Olugbala.
Alleluya !
f
Jesu yè; eyi daju,
Iku at’ ipá okunkun
Kì y’o lè yà ni kuro
Ninu ifẹ nla ti Jesu.
Alleluya !
Jesu yè; gbogbo ‘jọba
L’ ọrun, li aiye, di Tirè;
mf
Ẹ jẹ ki a ma tẹ̀le,
cr
Ki a lè jọba pẹlu Rẹ̀.
Alleluya ! Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites