Anglican Hymnal
Be not fretful, my soul, rest in hope;
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 216: Be not fretful, my soul, rest in hope;
Simi okan mi, ni ireti
Hymn:
216
Meter:
9.9.9.9
Season:
Asale Ajinde
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Simi ọkàn mi, ni ireti;
Ma bẹ̀ru bi ọla ti le ri,
p
Sa simi, iku papa l’ ọ̀na;
Iranṣẹ Ọba t’a ran si ọ.
mf
Simi ọkàn mi, Jesu ti ku,
Lotọ o sì ti jinde pẹlu;
Eyi to fun ireti mi, pe
Mo ku, mo sì yè, ninu Jesu.
Simi ọkàn mi, “O ti pari;”
Jesu pari ‘ṣẹ ìgbala Rè;
Simi, a ti ṣe gbogbo rẹ̀ tan
Lẹkan lai; igbala di tirẹ.
ff
Ogo fun Jesu ti O jinde!
Wọ t’a bi, t’a pa fun araiye:
Ogo funMetalọkan lailai!
Fun Baba, Ọmọ, ati Ẹmi. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites