Anglican Hymnal
Sabbath of the saints of old.
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 215: Sabbath of the saints of old.
Isimi awon mimo
Hymn:
215
Meter:
7.7.7.7.7.7
Season:
Asale Ajinde
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mp
Isimi awọn mimọ,
Ọjọ ohun ijinlẹ,
Ti Ẹlẹda ti bukùn,
Apẹrẹ isimi Rẹ̀.
cr
Oluwa simi ‘ṣẹ Rẹ̀,
O yà ‘jọ na si mimọ
p
Loni oku Oluwa
Nsimi ninu iboji,
A ti we l’aṣọ oku,
Lat’ ori titi d’ẹsẹ,
A si fi okuta se,
A si fi edidi di.
mp
Oluwa, titi aiye,
L’a o ma pa eyi mọ
A o t’ilẹkun pinpin,
K’ariwo ma ba wọle,
cr
A o fi suru duro,
Tit’ Iwọ o tun pada,
p
Gbogbo awọn t’o ti sùn,
Nwọn o wa ba Ọ simi;
Nwọn o bọ lọwọ lala,
cr
Nwọn nreti ipè ‘kẹhin,
f
T’a o di ẹda titun,
T’ayọ wa ki y’o l’opin.
mf
Jesu yọ wa nin’ ẹṣẹ,
K’a ba le ba wọn wọle,
cr
Ewu ati ‘sẹ́ y’o tán,
A o f’ayọ goke lọ,
f
A o ri Ọlọrun wa,
A o si ma sin lailai. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites