Anglican Hymnal
Father, forgive them: for thy know not
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 212: Father, forgive them: for thy know not
’Wo t’ o mbebe f’ ota Re
Hymn:
212
Meter:
7.7.7.6
Season:
Ijiya Jesu
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
“Baba, dariji wọn; nitori ti nwọn kò mọ̀ ohun ti nwọn nṣe.” --- Luk.23,34
mf
‘Wọ t’o mbẹbẹ f’ ọta Rẹ,
L’ or’ igi agbelebu;
Wipe, “fiji wọn Baba:”
p
Jesu, ṣanu fun wa.
mf
Jesu, jọ bẹbẹ fun wa,
Fun ẹ̀ṣẹ wa gbagbogbo;
A kò mọ̀ ohun t’ a nṣe:
p
Jesu, ṣanu fun wa.
Jẹ k’ awa ti nwá anu,
Dabi Rẹ l’ ọkàn n’ iwa,
‘Gbat’ a ba ṣe wa n’ibi:
p
Jesu, ṣanu fun wa.
“Loni ni iwọ o wa pẹlu mi ni Paradise” --- Luk. 23,43
mf
Jesu, ‘Wọ t’ o gbọ́ arò
Ole t’ o kú l’ ẹgbẹ́ Rẹ,
T’ o si mu d’ ọrun rere:
p
Jesu, ṣanu fun wa.
mf
Ninu ẹbi ẹ̀ṣẹ wa,
Jẹ k’ a tọrọ anu Rẹ,
K’ a ma pe orukọ Rẹ:
p
Jesu, ṣanu fun wa.
mp
Ranti awa ti nrahùn,
T’ a nwò agbelebu Rẹ;
F’ ireti mimọ́ fun wa,
p
Jesu, ṣanu fun wa.
“Obinrin, wò ọmọ rẹ. Wò iya rẹ.” ---Joh. 19: 26,27
mf
‘Wọ t’ o fẹ l’ afẹ dopin
Iya Rẹ t’ o nkan Rẹ,
Ati ọrẹ Rẹ ọwọ́n:
p
Jesu, ṣanu fun wa.
mf
Jẹ k’ a pin n’nu ìyà Rẹ,
K’ a má kọ ikú fun Ọ,
cr
Jẹ k’ a ri tọju Rẹ gba:
p
Jesu, ṣanu fun wa.
f
Ki gbogbo awa Tirẹ
Jẹ ọmọ ile kanna;
cr
‘Tori Rẹ, k’ a fẹ ra wa:
p
Jesu, ṣanu fun wa.
Ọlọrun mi, Ọlọrun mì eṣe ti iwọ fi kọ mi silẹ̀ --- Matt. 27,46
mf
Jesu, ‘Wọ ti ẹ̀ru mbà,
‘Gbat’ o si kù ‘Wọ nikan,
cr
Ti okunkun ṣu bò Ọ:
p
Jesu, ṣanu fun wa.
‘Gbati a ba npè lasan,
T’ ireti wa si jina;
N’nu okun na di wa mu:
p
Jesu, ṣanu fun wa.
B’ o dabi Baba kò gb´,
B’ o dabi ‘mọlẹ̀ kò si,
Jẹ k’ a f’igbagbọ ri Ọ,
p
Jesu, ṣanu fun wa.
“Orungbe ngbe mi.” --- Joh. 19,28
mf
Jesu, ninu ongbẹ Rẹ,
Ni ori agbelebu,
Wọ ti o fẹ wa sibẹ:
p
Jesu, ṣanu fun wa.
mf
Ma kongbẹ fun wa sibẹ,
Ṣiṣẹ mimọ́ l’ ara wa;
Tẹ́ ifẹ Rẹ na l’ ọrun;
p
Jesu, ṣanu fun wa.
mf
Jẹ k’ a kongbẹ ife Rẹ,
Ma ṣamọna wa titi,
Sibi omi ìye nì;
p
Jesu, ṣanu fun wa.
“O pari.” Joh. 19,30
mf
Jesu Olurapada,
‘Wọ t’ ṣe ‘fẹ Baba Rẹ,
T’ o si jiya ‘tori wa;
p
Jesu, ṣanu fun wa.
mf
Gba wa l’ ọjọ idamu,
Ṣe oluranlọwọ wa,
Lati ma t’ ọ̀na mimọ́;
p
Jesu, ṣanu fun wa.
mf
F’ imọlẹ Rẹ s’ ọna wa,
Ti y’o ma tàn titi lai,
Tit’ ao fi de ọdọ Rẹ:
p
Jesu, ṣanu fun wa.
“ Baba, li ọwọ Rẹ ni mo fi ẹmi mi le.” --- Luk 23,46
mf
Jesu, gbogbo iṣẹ Rẹ,
Gbogbo ijamu Rẹ pin;
O jọw’ ẹmi Eẹ lọwọ;
p
Jesu, ṣanu fun wa.
mf
‘Gbat’ ikú ba dé bá wa,
Gbà wa lọwọ ọta wa;
f
Yọ wa ni wakati na,
p
Jesu, ṣanu fun wa.
Ki ikú at’ iye Re.
Mu ore-ọfẹ ba wa,
Ti yio mu wa d’ oke;
p
Jesu, ṣanu fun wa. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites