Anglican Hymnal
O perfect life of love!
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 209: O perfect life of love!
Ife lo to bayi
Hymn:
209
Meter:
S.M (6.6.8.6)
Season:
Ijiya Jesu
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mp
Ifẹ lo to bayi!
Ohun gbogbo pari,
O ti pari gbogbo iṣẹ
T’o tori rẹ̀ w’aiye.
Ohun ti Baba fẹ,
Ni Jesu ti ṣe tan:
p
Wahala ati ìyà Rẹ̀
cr
Mu Iwe Mimọ ṣẹ;
Kò s’ irora wa kan,
Ti Jesu ko jẹ rì;
Gbogbo ẹ̀dun at’ aniyan,
L’ ọkàn Rẹ̀ si ti mọ̀.
L’ ori t’a f’ẹgun dé,
At’ ọkàn Rẹ̀ mimọ,
L’ a kó gbogbo ẹṣẹ wa le,
K’ O ba le wò wa san.
p
Ifẹ lo mu k’O kú
Fun emi otoṣi;
cr
‘Wọ Etutu f’ẹṣẹ̀ gbogbo,
Mo f’igbagbọ rọ̀ mọ.
mf
Nigba aini gbogbo,
Ati n’itẹ ‘dajọ,
cr
Jesu, ododo Rẹ nikan,
Ni igbẹkẹle mi.
mf
Jọ, ṣiṣẹ ninu mi,
Bi O ti ṣe fun mi,
cr
Si jẹ ki ifẹ mi si Ọ,
Ma fi ore Rẹ hàn. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites