Anglican Hymnal
Glory be to Jesus
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 200: Glory be to Jesus
Ogo ni fun Jesu
Hymn:
200
Meter:
6.5.6.5
Season:
Ijiya Jesu
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
Ogo ni fun Jesu
p
T’o f’ irora nla
cr
Ta ẹ̀jẹ Rẹ̀ fun mi
Lati ìha Rẹ̀.
f
Mo r’ ìye ailopin
Ninu ẹjẹ na;
Iyọ́nu Rẹ̀ sa pọ̀,
Ore Rẹ̀ ki tán.
f
Ọpẹ ni titi lai,
F’ẹjẹ ‘yebiye
T’o rà aiye pada,
Kuro n’nu egbe.
mf
Ẹjẹ Abel’ nkigbe
Si ọrun f’ ẹsan;
Ṣugb’ ẹ̀jẹ Jesu nké
f
Fun ‘darijì wa.
p
Nigbati a bu wọ́n
Ọkàn ẹ̀ṣẹ wa,
Satan, n’ idamu rẹ̀,
F’ẹru sa jade.
f
Nigbat’ aiye ba nyọ̀,
T’o ngbe ‘yìn Rẹ̀ ga,
Awọn ogun Angẹl
A ma f’ ayọ̀ gbe.
f
Njẹ, ẹ gbohùn nyin ga,
Ki ìró na dún !
ff
Kikan lohùn goro,
Yin Ọdagutan. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites