Anglican Hymnal
Hosanna unto David's son
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 196: Hosanna unto David's son
Hosanna s’Omo Dafidi
Hymn:
196
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Ojo 'simi Ope
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
“Hosanna, s’Ọmọ Dafidi:”
ff
Hosanna! ẹ kọrin!
“Olubukun l’ẹniti mbọ̀
Lorukọ Oluwa.”
f
“Hosanna s’Ọmọ Dafidi:”
L’ẹgbẹ Angẹli nké;
ff
Gbogb’ ẹda, ẹ jùmọ gberin,
Hosanna s’Ọba wa.
Hosanna ! awọn Heberu
Jà im’ọpẹ s’ọna;
Hosanna ! a mu ẹ̀bun wá
Fi tun ọ̀na Rẹ ṣe.
ff
T’àgba t’ewe nke, Hosanna!
p
K’ijiya Rẹ to de;
L’oni, a sì nkọ Hosanna!
B’o ti njọba lokè.
B’o ti gbà ‘yìn wọn nigbana,
p
Jọ, gbà ẹ̀bẹ wa yi!
Lọrun, k’a le b’Angẹl kọrin,
ff
Hosanna s’Ọba wa. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites