Anglican Hymnal
My God, my Father, dost Thou call
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 188: My God, my Father, dost Thou call
Olorun, Baba mi, ’Wo npe
Hymn:
188
Meter:
L.M (8.8.8.8)
Season:
Lenti, Isoji
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mp
Ọlọrun, Baba mi, ‘Wọ npè
Aṣako ọmọ Rẹ mọra?
cr
Iwọ o ha dariji mi?
p
Mo de, mo de, jọ gbà mi la.
mp
A! Jesu, Iwọ nrekọja
Pẹlu ore at’ agbara?
cr
‘Wọ kò ha ngbọ́ igbe mi bi?
p
Mo de, mo de, ṣanu fun mi.
mp
A! Ẹmi Mimọ, Iwọ ni?
Ọrẹ ti mo ti ṣati pẹ!
‘Wọ ha mbẹ̀bẹ fun mi sibẹ?
p
Mo de, mo de, m’ailera le.
cr
Mo de, Oluwa, ifẹ Rẹ
Ni o nrọ̀ mi t’o sì nfà mi:
f
Mo wolọ̀ lẹsẹ Rẹ, ki mmọ̀
B’o ti dùn lati jẹ Tire. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites