Anglican Hymnal
Not all the blood of beasts
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 183: Not all the blood of beasts
Gbogbo eje eran
Hymn:
183
Meter:
S.M (6.6.8.6)
Season:
Lenti, Isoji
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Gbogbo ẹjẹ ẹran,
Ti pẹpẹ awọn Ju;
Kò lè f’ ọkàn l’ alafia,
Kò lè wẹ eri nù.
Kristi Ọd’agutan,
p
M’ẹ̀ṣẹ wa gbogbo lọ;
Ẹbọ t’ o ni orukọ nla,
T’ o ju ẹjẹ wọn lo.
mf
Mo f’ igbagbọ gb’ ọwọ
Le ori Rẹ ọwọ́n;
B’ ẹnt’ o ronupiwada,
Mo jẹ́wọ ẹ̀ṣẹ mi.
Ọkàn mi npadà wò
p
Ẹrù t’ Iwọ ti rù;
Nigbati a kàn Ọ mọ ‘gi,
Ẹṣẹ rẹ̀ wa nibẹ.
f
Awa nyọ̀ ni ‘gbagbọ,
Bi egún ti kurò,
ff
Awa nyin Ọdọ-agutan,
A nkọrin ifẹ rè. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites