Anglican Hymnal
Come, ye sinners, poor and wretched
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 175: Come, ye sinners, poor and wretched
Otosi elese, e wa
Hymn:
175
Meter:
8.7.8.7.11
Season:
Lenti, Isoji
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Otoṣi ẹlẹṣẹ, ẹ wa,
Wa ni wakati anu;
Jesu ṣetan lati gbà nyin,
O kun f’anu at’ ifẹ:
cr
O si le ṣe, o mura tan, má foiya.
mf
Ẹnyin alaini, ẹ wa gba
Ogo Ọlọrun lọfẹ,
‘Gbagbọ totọ, ‘ronu totọ,
Or’ ọfẹ ti o nfà wa,
cr
Wa ‘dọ Jesu, laini owo, sa wa rà.
mp
Má jẹ k’ ọkàn nyin da nyin ró,
Maṣe ro ti aiyẹ nyin;
Gbogbo yiyẹ t’ O mbere ni,
Ki ẹ sa mọ aini nyin:
cr
‘Yi l’ O fun nyin; ‘tanṣan Ẹmi l’ ọkàn.
mp
Ẹnyin t’ẹrù npa, t’arẹ mu,
T’ ẹ sọnu r’ẹ si ṣègbe,
Bi ẹ duro tit’ ẹo fi, sàn
Ẹ kì yio wà rara:
cr
F’ẹlẹṣẹ ni, On kò wá f’ olododo.
mf
Ọlọrun goke l’awọ́ wa,
O nfi ẹjẹ Rẹ̀ bẹ̀bẹ̀,
cr
Gbe ara le patapata;
Má gbẹkẹle ohun mi:
f
Jesu nikan l;o le ṣ’ẹlẹṣẹ l’ore.
ff
Angẹli at’ awọn mimọ
Nkọrin ‘yin Ọdagutan;
Gbohungbohun Orukọ Rẹ̀
Si gba gbogbo ọrun kan:
Halleluya! ẹlẹṣẹ le gberin na. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites