Anglican Hymnal
Just as I am, without one plea
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 172: Just as I am, without one plea
Bi mo ti ri laisawawi
Hymn:
172
Meter:
8.8.8.6
Season:
Lenti, Ironupiwada
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
p
Bi mo ti ri --- laiṣawawi,
Ṣugbọn nitori ẹjẹ Rẹ;
B’ o si ti pè mi pe ki nmà---
cr
Olugbala, mo de.
p
Bi mo ti ri --- laiduro pẹ,
Mo fẹ k’ ọkàn mi mọ́ toto,
S’ọdọ Rẹ t’o le wẹ̀ mi mọ ,
cr
Olugbala, mo de.
Bi mo ti ri --- b’o tilẹ jẹ
Ijà l’ode, ija ninu;
Ẹru l’ode, ẹru ninu,---
cr
Olugbala, mo de.
p
Bi mo ti ri --- òṣi, are,
cr
Mo si nwa imularada;
Iwọ l’o le s’awotán mi, ----
Olugbala, mo de.
mf
Bi mo ti ri --- ‘Wọ o gbà mi,
Wọ o gbà mi t’ọwọ t’ẹsẹ;
cr
‘Tori mo gbà ‘leri Rẹ gbọ,----
Olugbala, mo de.
p
Bi mo ti ri ---- ifẹ Tirẹ,
cr
L’o ṣẹtẹ̀ mi patapata;
f
Mo di tirẹ, tire nikan,---
Olugbala, mo de. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites