Anglican Hymnal
Sun of my soul, O Savior dear
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 16: Sun of my soul, O Savior dear
Iwo Imole okan mi
Hymn:
16
Meter:
L.M (8.8.8.8)
Season:
Orin Ale
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Iwo Imọlẹ ọkàn mi,
Li ọdọ Rẹ oru kò si,
Ki kuku aiye má bò Ọ,
Kuro l’ oju iranṣẹ Rẹ.
pp
Nigbat’ orun alẹ didun
Ba npa ipenpeju mi de,
K’ erò mi je lati simi
Lai, l’aiya Olugbala mi.
mf
Ba mi gbe l’ orọ tit; alẹ,
Laisi Rẹ, emi kò lè wà;
p
Ba mi gbe gbat’ ilẹ ba nṣú,
Laisi Rẹ, emi ko le kù.
Bi otoṣi ọmọ Rẹ kan
Ba tapa s’ọrọ Rẹ loni,
cr
Oluwa ṣiṣe ore Rẹ,
Má jẹ k’o sùn ninu ẹ̀ṣẹ.
mf
Bukun fun awọn alaisan,
Pèse fun awọn talaka;
di
K’orun alawẹ̀ l’ alẹ yi,
pp Dabi orun ọmọ titun.
cr
Sure tun wa nigbat’ a ji,
K’ a to m’ ohun aiye yi ṣe,
f
Titi awa o de b’ ìfe
T’ a o si de ìjọba Rẹ. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites