Anglican Hymnal
O Lord hear my supplications
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 159: O Lord hear my supplications
Oluwa, gbo aroye mi
Hymn:
159
Meter:
L.M (8.8.8.8)
Season:
Lenti, Ironupiwada
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Oluwa, gbọ aroye mi,
Gbọ adura ikọkọ mi;
Lọdọ Rẹ nikan, Ọba mi,
L’ emi o ma wá iranwọ.
mf
L’ orọ Iwọ o gbohùn mi;
L' afẹmọjumọ ọjọ na;
Ni ọdọ Rẹ l’emi o wò,
Si Ọ l’ emi o gbadura.
Ṣugbọn nigb’ ore-ọfẹ Rẹ
Ba mu mi de agbala Rẹ,
Ọdọ Rẹ l’ em’ o tẹju mọ.
Nibẹ ngo sìn Ọ n’ irẹlẹ.
f
Jẹ k’ awọn t’ o gbẹkẹle Ọ,
ff
L’ohun rara wi ayọ̀ won:
Jẹ k’ awọn t’Iwọ pamọ yọ̀,
Awọn t’ o fẹ orukọ Rẹ.
f
Si olododo l’ Oluwa
O nà ọwọ ibukun Rẹ̀;
Ojurere Rẹ̀ l’ enia Rẹ̀
Yio si fi ṣe asa wọn. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites