Anglican Hymnal
It is not meet for Saints to fear
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 153: It is not meet for Saints to fear
Ko to k’ awon mimo beru
Hymn:
153
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Lenti, Ironupiwada
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Kò tọ k’ awọn mimọ́ bèru,
Ki nwọn sọ ‘reti nu:
‘Gba nwọn kò reti ranwọ Rẹ̀,
Olugbala y’o de.
Nigbati Abram mu ọbọ,
Ọlọrun ni, “Duro”;
Agbo ti o wà lọhun ni,
Y’o dipo ọmọ na”.
p
‘Gba Jona rì sinu omi,
Ko rò lati yọ mọ;
Ṣugbọn Ọlọrun rán ẹja,
T’ o gbe lọ s’ ebute.
B’ iru ipa at’ ifẹ yi
Ti pọ l’ ọ̀rọ Rẹ̀ to!
Emi ba ma k’ aniyan mi,
Le Oluwa lọwọ!
f
Ẹ duro de iranwọ Rẹ̀,
B’ o tilẹ̀ pẹ, Duro,
B’ ileri na tilẹ̀ falẹ̀,
Ṣugbọn kò le pẹ de. Amn.
« Back to Hymn List
View Favourites