Anglican Hymnal
When they turned against mount Zion
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 150: When they turned against mount Zion
Nigba nwon kehin si Sion
Hymn:
150
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Lenti, Ironupiwada
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Nigbà nwọn kẹhin si Sion,
A! ọpọ n’iye wọn;
Mo ṣeb’ Olugbala wi pe,
p
‘Wọ fẹ kọ̀ mi pẹlu?
T’ emi t’ ọkàn b’ iru eyi,
Afi b’ O dì mi mu;
Nkò le ṣe ki nma fà sẹhin,
K’ emi si dabi wọn.
f
Mo mọ̀, Iwọ l’o l’ agbara
Lati gbà otoṣi;
Ọdọ tani emi o lọ,
Bi mo k’ ẹhin si Ọ?
f
O da mi loju papa pe
Iwọ ni Kristi na!
Ẹni t’ o ni ẹmi iye,
Nipa ti ẹjẹ Rẹ̀.
mf
Ohùn Rẹ f’ isimi fun mi,
O si l’ ẹ̀ru mi lọ;
Ifẹ Rẹ l’ o lè mu mi yọ̀
O si ti f’ ọkàn mi
Bi ‘bere yi ti dùn mi to,
p
“Pe emi o lọ bi?”
f
Oluwa, ni ‘gbẹkẹle Rẹ,
Mo dahun pe “Bẹkọ.” Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites