Anglican Hymnal
Praise to the Holiest in the height
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 139: Praise to the Holiest in the height
Iyin f’Eni Mimo julo
Hymn:
139
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Ifihan, Mission
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Iyin f’Ẹni Mimọ julọ,
Loke ati n’ilẹ;
Ọrọ Rẹ̀ gbogbo je iyanu,
Gbogb’ ọna Rẹ̀ daju/
mf
Ọgbọn Ọlọrun ti pọ to!
p
Gbat’enia ṣubu;
cr
Adam keji wá s’oju ‘ja,
f
Ati lati gbàla.
mf
Ọgbọn ifẹ! P’ẹran ara
p
T’ o gbe Adam ṣubu,
cr
Tun b’ọta ja ija ọtun,
f
K’ o jà k’o si ṣẹgun.
mf
Ati p’ẹbùn t’o j’ or’ọfẹ,
Sọ ara di ọtun;
p
Ọlọrun papa Tikarẹ̀
J’Ọlọrun ninu wa.
Ifẹ ‘yanu! Ti Ẹniti
O pa ọta enia,
Ninu àwọ awa enia
Jẹ irora f’enia.
Nikọkọ ninu ọgba ni,
Ati lori igi,
To si kọ́ wa lati jiya,
To kọ́ wa lati kú.
f
Iyin f’Ẹni Mimọ julọ,
Loke ati n’ile;
Ọrọ Rẹ gbogbo jẹ ‘yanu,
Gbogb’ ọ̀na Rẹ̀ daju. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites