Anglican Hymnal
Look with compassion on the coasts
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 133: Look with compassion on the coasts
E fi oju iyonu wo
Hymn:
133
Meter:
8.7.8.7.8.7
Season:
Ifihan, Mission
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Ẹ fi oju iyọnu wó
Okun ilẹ keferi:
Sa wò bi ọpọlọpọ wọn
Ti njowere ‘nu ẹ̀ṣẹ;
p
Okunkun bò, Okunkun bò,
Oju ilẹ aiye wa.
Imọlẹ ẹni okunkun,
Dide, mu ibukun wá!
Imọlẹ f’ awọn Keferi,
Wa, pẹlu ‘mularada;
Ki gbogb’ Ọba, Ki gbogb’ Ọba,
Wá sinu imọlẹ na.
Jẹ k’ awọn Keferi ti mbọ
Igi ati okuta;
Wà lati fi oribàlẹ
Fun Ọlọrun alayè
Jẹ k’ogo Rẹ, Jẹ k’ogo Rẹ,
Bò gbogbo ilẹ aiye.
f
Iwọ t’ a f’ ipa gbogbo fun,
Sọrọ̀ na! pa aṣẹ Rẹ;
Jẹ ki ẹgbẹ oniwasu
Tan ‘rukọ Rẹ ka kiri;
Wà pẹlu wọn, Wà pẹlu wọn,
Oluwa, titi d’ opín. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites