Anglican Hymnal
God, all the human kind are but
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 129: God, all the human kind are but
Olorun, gbogbo araiye
Hymn:
129
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Ifihan, Mission
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Ọlọrun, gbogbo araiye
Ni ẹda ọwọ Rẹ;
Ati ni iṣẹ Rẹ t’a nri
Ogo didan Rẹ ntàn.
Ṣugbọn ifẹ nla Rẹ ti ràn
Ihinrere s’aiye;
Ti nfi ọ̀rọ ore nla hàn,
T’ o ti fi ṣe ‘ṣura,
‘Gbawo n’ihin yi yio tàn
Yi gbogbo aiye ká,
Ti gbogbo ẹ̀ya at’ ọkàn
Yio gbọ́ iro na?
‘Gbawo ni ọmọ Afrika
Y’o m’ adùn ọ̀rọ na;
At’ awọn t’ o ti s’ẹrú pẹ,
Yio di omnira?
‘Gbawo ni awọn keferi
T’ o wà ni okunkun;
Yio joko l’ẹsẹ Jesu,
Lati kọ́ ore Rẹ?
Oluwa bukun fun iṣẹ
Itanka ọ̀rọ Rẹ;
K’ o si kọ ‘le iyin Rẹ le
Itẹ ẹ̀ṣẹ t’ o wó. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites