Anglican Hymnal
He that sitteth at the right hand
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 128: He that sitteth at the right hand
Eni t’ o joko low’ otun
Hymn:
128
Meter:
8.7.8.7
Season:
Ifihan, Mission
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
Ẹni t’ o joko lọw’ ọtun
Ti Baba l’ oke ọrun,
On na l’o si mbẹbẹ fun wa
Nitori k’ a ba lè la.
O mbẹbẹ, k’ a ab lè gba wa
Lọwọ Oludanwo nì;
Ati n’nu ẹ̀ṣẹ, on ‘binu
At’ idajọ ti mbọwá.
O mbẹbẹ k’ a ba lè jogun
Ilẹ ti Ọba ọrun;
Tani l’ aiye, t’ o lè rohin
Ogo ati ọla na.
On nikan ni Alagbawi
Fun awọn ẹni Tirẹ̀;
Ẹjẹ ẹnikẹni kò lè
Pa igbese t’ a jẹ ré.
Iwọ nikan l’ Ọmọ Baba
Iwọ l’Ọba titi lai;
Enia j’ẹlẹṣẹ pupọ;
Angẹli ni ‘ranṣẹ Rẹ̀.
Iwọ si jẹ Olododo
T’ o pé lọdọ Baba Rẹ;
Bẹ gẹgẹ ni orukọ Rẹ
Gbogbo ileri y’o ṣẹ. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites