Anglican Hymnal
The Lord God has made Jesus Christ
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 126: The Lord God has made Jesus Christ
Olorun ti fi Jesu se
Hymn:
126
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Ifihan, Mission
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Ọlọrun ti fi Jesu ṣe
Etutu fun ẹ̀ṣẹ;
On na l’ ọkàn mi duro tì,
Ninu igbagbọ mi.
p
Ọlọrun si ni iyọnú
Si ẹjẹ Ọmọ Rẹ̀;
p
Ọmọ si ti mu ẹjẹ nà
Wọ ibi mimọ́ lọ.
Nibẹ ni ẹjẹ ibuwọn
Nsọrọ rere fun wa;
Nibẹ ni turari didun
Ti Alufa nla wà.
f
Angẹli nwo, ẹnu yà wọn;
p
Nwọn si ntẹri wọn ba
Nitori anu Ọlọrun
T’o f’ẹjẹ gba ni là.
Emi o ma fi igbagbọ
Sunmọ ‘bi mimọ́ yi;
Ngo ma kọrin s’ Olugbala,
Ngo bẹ k’o gb’ọkàn mi.
A ya orin mi si mimọ,
Nipa ẹjẹ Rẹ̀ na;
O si dùn nipa igbagbọ,
O jẹ ‘tọwò ọrun. Amin
« Back to Hymn List
View Favourites