Anglican Hymnal
Work on and never be weary
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 125: Work on and never be weary
Ma sise lo, mase sare
Hymn:
125
Meter:
L.M (8.8.8.8)
Season:
Ifihan, Mission
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Ma ṣiṣẹ lo, máṣe ṣarẹ̀,
Fi ayọ̀ ṣiṣẹ Baba rẹ;
Bayi ni Jesu ṣe l’ aiye,
Ko ha ye, k’ awa ko ṣe bẹ?
f
Ma ṣiṣẹ lọ, lojojumọ,
p
Okunkun aiye fẹrẹ de;
f
Mura si ‘ṣẹ, màṣe ṣ’ọlẹ,
Ko ba lè gba ọkan rẹ là.
p
Pupọ pupọ l’ awọn t’ o kú
Ti nwọn kò m’ ireti ọrun;
Gbe ina ‘gbagbọ rẹ, ma fi,
Ma fi si okunkun aiye.
f
Ma ṣiṣẹ lọ, ma yọ̀ pẹlu,
Lẹhin iṣẹ ‘wọ o simi;
O fẹrẹ gbohun Jesu na,
ff
Y’o ke tantan pe, “Emi de.” Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites