Anglican Hymnal
Arm of the Lord! awake, awake!
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 116: Arm of the Lord! awake, awake!
Ji, apa Olorun, k’ o ji
Hymn:
116
Meter:
L.M (8.8.8.8)
Season:
Ifihan, Mission
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Ji, apa Ọlọrun, k’ o ji,
Gbe ‘pa Rẹ wọ̀, mì orilẹ̀;
Ni sisin Rẹ, jẹ k’ aiye ri
Iṣẹgun iṣẹ anu Rẹ.
T’ itẹ Rẹ wi fun keferi,
“Emi Jehofah Ọlọrun.”
Ohùn Rẹ y’o d’ere wọn ru
Yio wo pẹpẹ wọn lulẹ̀.
mf
Má jẹ k’ a ta ‘jẹ́ silẹ mọ́,
Ẹbọ asan fun enia;
Si ọkàn gbogbo ni k’ lò
Ẹjẹ t’o tiha Jesu yọ.
f
Olodumare, n’ apa Rẹ
F’ opin s’ itanjẹ Imale:
J’ ẹ̀wọn isin èke Popu,
Dà ‘binu agberaga ro.
mf
Ki ‘gbojurere Sion de,
K’ a m’ẹyà Israel wá ‘le;
N’ iyanu k’a f’oju wa ri
Keferi, Ju, l’agbo Jesu.
f
Olodumare, lọ́ ‘fẹ Rẹ,
L’ororukọ, ilẹ gbogbo;
Ki gbogb’ ọta wolẹ fun Ọ.
Ki nwọn gba Jesu l’ Oluwa. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites