Anglican Hymnal
Behold, what star is this
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 113: Behold, what star is this
Irawo wo l’eyi
Hymn:
113
Meter:
S.M (6.6.8.6)
Season:
Ifihan, Mission
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Irawọ wo l’eyi?
Wò b’o ti dara to,
Amọnà awọn keferi
S’ọdọ Ọba ogo.
Wò awọn amoye
Ti ila-orùn wá;
Nwọn wá fi ori balẹ fun
Jesu Olubukun.
Imọlẹ ti Ẹmi.
p
Má ṣai tan n’ ilu wa;
Fi ọ̀na han wa k’ a le tọ,
Emmanueli wá.
f
Gbogbo irun-malẹ̀,
Ati igba-malẹ̀,
Ti a mbọ n’ ilẹ keferi,
K’ o yàgo fun Jesu.
mf
Ki gbogbo Abọrẹ̀
Ti mbẹ ni Afrika.
Jẹ amoye li otitọ,
Ki nwọn gb’ẹbọ Jesu.
Baba Ẹlẹda wa,
Ti o fi Jesu hàn
Awọn keferi igbani;
Fi hàn fun wa pẹlu. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites