Anglican Hymnal
Glory to thee, my God, this night,
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 11: Glory to thee, my God, this night,
Ogo f’ Olorun l’ ale yi
Hymn:
11
Meter:
L.M (8.8.8.8)
Season:
Orin Ale
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Ogo f’Ọlọrun, l’alẹ yi
Fun gbogbo ore imọlẹ.
Ṣọ́ mi, Ọba awọn ọba
Labẹ ojiji ìyẹ Rẹ.
mp
Oluwa, f’ẹ̀ṣẹ mi jì mi,
Nitori Ọmọ Rẹ loni,
K’ emi lè wà l’alafia,
Pẹlu Iwọ ati aiye.
Kọ mi ki nwà, ki nlè ma wò
Iboji tẹnmen b’ẹni mi;
p
Kọ mi ki nkú, ki nle dide
cr
Ninu ogo l’ọjọ ‘dajọ.
mf
Jẹ k’ ọkàn mi lè sún le Ọ,
K’ orun didun p’oju mi de;
Orun ti y’o m’ara mi le
Ki nlè sin Ọ li owurọ̀.
p
Bi mo ba dubulẹ laisùn,
F’erò ọrun kun ọkàn mi:
Mà jẹ ki nlala buburu,
Mà jẹ k’ ipa okùn bò mi.
ff
Yin Oluwa gbogbo ẹda,
Ti mbẹ nisalẹ aiye yi:
Ẹ yin loke, ẹda ọrun,
Yin Baba, Ọmọ on Ẹmi. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites