Anglican Hymnal
O Lord God and Lord of the earth
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 106: O Lord God and Lord of the earth
Olorun Oluwa aiye
Hymn:
106
Meter:
C.M (8.6.8.6)
Season:
Ifihan
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
f
Ọlọrun Oluwa aiye
‘Wọ t’ o rán ‘rawọ̀ Rẹ,
Lati mu awọn amoye
M’ ọ̀na ibugbe Rẹ.
‘Gbawo’ ni ‘mọlẹ ọ̀rọ Rẹ
Y’o tàn yi ‘lu wa ka?
Ti aiya awọn ọba wa
Y’o fà si ọdọ Rẹ?
T’ awọn ijoye wa gbogbo
Yio wá juba Rẹ;
Ti ohun ti a bi wọn bi
Y’o j’ asan loju wọn?
p
Ilẹ wa kun fun okunkun
Okun aiye-baiye,
Ohun inira ni fun wa,
Lati jade n’nu rè.
f
Ṣugbon Ọlọrun Oluwa,
Tàn ‘mọlẹ s’òkun wa,
K’ a lè ri wère ‘ṣina wa
K’ a le kọ̀ wọn silẹ̀.
ff
‘Gbana ilu wa y’o logo
Y’o m’ọrẹ fun Ọ wá;
Ọrẹ t’ iṣe atinuwá,
At’ isìn otitọ. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites