Anglican Hymnal
Beloved Son of the Father
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 105: Beloved Son of the Father
’Wo Omo ayanfe Baba
Hymn:
105
Meter:
L.M (8.8.8.8)
Season:
Ifihan
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
‘Wọ Ọmọ ayanfẹ Baba,
Wá lati gbà ilẹ ini,
Ti Baba ti pamọ lailai
Fun ijọba Rẹ ailopin.
Wá f’ ara Rẹ hàn araiye
Wá ki gbogbo wọn juba Rẹ;
Niwaju Rẹ, gbogbo ahọn
Ni y’o jẹwọ itoye Rẹ.
Awọn t’ o wà n’ ila-orùn
Ẹgbẹgbẹrun! Nwọn ti pọ to!
Pẹlu awọn t’ ìwọ-orùn
Yio sìn Ọba ologo.
Gbogbo ariwa, on gusu,
Yio pe orukọ nla Rẹ;
Keferi, ati Ju pẹlu
Nwọn o wá s’ abẹ oyè Rẹ.
Okunkun ṣú bò wọn mọlẹ;
Ọlọrun Oluwa ‘mọlẹ,
ff
Tàn imọlẹ Ihin-rere
Ka gbogbo orilẹ-ede.
f
Yara jẹ ki ‘jọba Rẹ de,
Gbọ́ adura yi, Oluwa;
Ti gbogbo ẹ̀ya at’ ède
Y’o fi mọ̀ Ọ l’Olugbala. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites