Anglican Hymnal
As with gladness men of old
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 102: As with gladness men of old
B’ awon ara igbani
Hymn:
102
Meter:
7.7.7.7.7.7
Season:
Ifihan
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
B’ awọn ará igbanì
Ti f’ayọ̀ ri ‘ràwọ na;
Bi nwọn ti f’inu didùn
Tẹle ‘mọlẹ didan rẹ̀;
Bẹ̀, Oluwa Olore
Ni k’a mù wa d’ọdọ Rẹ.
mf
Bi nwọn ti fi ayọ lọ
Si ibujẹ ẹran ná;
Ti nwọn sì wolẹ nibẹ
F’ Ẹni t’ọrun t’aiye mbọ;
Gẹgẹ bẹ mo l’a má yọ̀
Lati wá s’ itẹ anu.
Bi nwọn ti mu ọrẹ wá
Si ibujẹ ẹran na;
Ba ni k’ awa ma f’ayọ̀
Mimọ t’ẹṣẹ kò bajẹ
Mu ‘ṣura wa gbogbo, wá
Sọdọ Rẹ, Jesu Ọba.
p
Jesu mimọ, pa wa mọ,
L’ọna toro l’ọjọjọ;
cr
‘Gbat’ ohun aiye ba pin,
M’ọkàn wa de ilu, ti
f
‘Ràwọ kò nṣanmọ̀na mọ;
‘Biti nwọn nwò ogo Rẹ.
Ni ‘lu ọrun mimọ na,
Nwọn kò wá imọlẹ mọ;
‘Wọ l’Orùn rẹ̀ ti ki wọ;
‘Wọ l’ayọ̀ at’ ade rẹ̀;
Nibẹ titi l’ao ma kọ
Halleluya s’Ọba wa. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites