Anglican Hymnal
The heavenly controller
Read, listen, and switch between English and Yoruba lyrics.
All Hymns
Favourites
Hymn 100: The heavenly controller
Alakoso ti orun
Hymn:
100
Meter:
7.7.7.7
Season:
Odun Titun
♡
Add Favourite
Your browser does not support the audio element.
View English
mf
Alakoso ti ọrun,
Alànu at’ Ọlọgbon;
Igbà mi mbẹ lọwọ Rẹ,
Opin gbogbo l’aṣẹ Rẹ.
Aṣẹ Rẹ l’o da aiye
Ati ibi mi pẹlu;
Obi, ilẹ, on igba;
Nipa Rẹ ni gbogbo wọn.
f
Igb’aisàn, on ilera,
Igbà iṣẹ on ọrọ;
Igbà ‘danwò, ibinu,
Igbà ‘ṣẹgun, iranwọ.
Igba iridi Eṣu
Igba ‘tọ ‘fẹ Jesu wọ̀,
Nwọn o wá, nwọn o si lọ,
B’Ọre wa ọrun ti fe.
ff
Iwọ Olore-ọfẹ,
‘Wọ ni mo f’ẹmi mi fun,
Emi jẹwọ ifẹ Rẹ,
Emi tẹriba fun Ọ. Amin.
« Back to Hymn List
View Favourites